Jeremiah 22:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.
Jeremiah 22:11 in English
Jeremiah 22:11 · Berean Standard Bible
For this is what the LORD says concerning Shallum * son of Josiah, king of Judah, who succeeded his father Josiah but has gone forth from this place: “He will never return,
Context
9Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ” 10Nítorí náà má ṣe sọkún nítorí ọba tí ó ti kú tàbí ṣọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ sọkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú
nítorí kì yóò padà wá mọ́
tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i. 11Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́. 12Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.” 13“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo,
àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́
tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán
láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.