Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé, ‘Níbo ni Olúwa wà?’ Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi. Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.

Jeremiah 2:8 in English

Jeremiah 2:8 · Berean Standard Bible

The priests did not ask, ‘Where is the LORD?’ The experts in the law no longer knew Me, and the leaders rebelled against Me. The prophets prophesied by Baal and followed useless idols.

Context

6Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà, tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, tí ó mú wa la aginjù já, tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò, ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’ 7Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. 8Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé, ‘Níbo ni Olúwa wà?’ Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi. Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán. 9“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,” ni Olúwa wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ. 10Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó, ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi; kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.