Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó, ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi; kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?

Jeremiah 2:10 in English

Jeremiah 2:10 · Berean Standard Bible

Cross over to the coasts of Cyprus * and take a look; send to Kedar and consider carefully; see if there has ever been anything like this:

Context

8Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé, ‘Níbo ni Olúwa wà?’ Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi. Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán. 9“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,” ni Olúwa wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ. 10Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó, ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi; kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀? 11Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.) Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì. 12Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.