Jeremiah 2:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 2:12 in English
Jeremiah 2:12 · Berean Standard Bible
Be stunned by this, O heavens; be shocked and utterly appalled,” declares the LORD.
Context
10Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi;
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀? 11Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà?
(Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì. 12Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”
ni Olúwa wí. 13“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì,
wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Èmi orísun omi ìyè,
wọ́n sì ti ṣe àmù,
àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró. 14Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí?
Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.