Jeremiah 2:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,” ni Olúwa wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ.
Jeremiah 2:9 in English
Jeremiah 2:9 · Berean Standard Bible
Therefore, I will contend with you again, declares the LORD, and I will bring a case against your children’s children.
Context
7Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra. 8Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,
‘Níbo ni Olúwa wà?’
Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,
àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.
Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,
wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán. 9“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”
ni Olúwa wí.
“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ. 10Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi;
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀? 11Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà?
(Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.