Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́, Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún.

Jeremiah 2:23 in English

Jeremiah 2:23 · Berean Standard Bible

“How can you say, ‘I am not defiled; I have not run after the Baals’? Look at your behavior in the valley; acknowledge what you have done. You are a swift young she-camel galloping here and there,

Context

21Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá. Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́? 22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,” ni Olúwa Olódùmarè wí. 23“Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́, Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún. 24Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ, ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara, nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀. 25Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.