Jeremiah 2:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá. Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́?
Jeremiah 2:21 in English
Jeremiah 2:21 · Berean Standard Bible
I had planted you like a choice vine from the very best seed. How could you turn yourself before Me into a rotten, wild vine?
Context
19Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín
ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí
mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti
ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ
nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,
ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 20“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù,
ìwọ sì já ìdè rẹ;
ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’
Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni
àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀
ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà. 21Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá.
Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi
di àjàrà búburú àti aláìmọ́? 22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà
tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ
síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,”
ni Olúwa Olódùmarè wí. 23“Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́,
Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?
Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;
wo ohun tí o ṣe.
Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ
tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.