Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,” ni Olúwa Olódùmarè wí.

Jeremiah 2:22 in English

Jeremiah 2:22 · Berean Standard Bible

Although you wash with lye and use an abundance of soap, the stain of your guilt is still before Me,” declares the Lord GOD.

Context

20“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ; ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà. 21Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá. Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi di àjàrà búburú àti aláìmọ́? 22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,” ni Olúwa Olódùmarè wí. 23“Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́, Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún. 24Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ, ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara, nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.