Jeremiah 2:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni! Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì, àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’
Jeremiah 2:25 in English
Jeremiah 2:25 · Berean Standard Bible
You should have kept your feet from going bare and your throat from being thirsty. But you said, ‘It is hopeless! For I love foreign gods, and I must go after them.’
Context
23“Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́,
Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?
Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;
wo ohun tí o ṣe.
Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ
tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún. 24Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù
tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ,
ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀?
Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara,
nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀. 25Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà,
àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni!
Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,
àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’ 26“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—
àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,
àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú. 27Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’
àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’
wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,
wọn kò kọ ojú sí mi
síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,
wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.