Jeremiah 12:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ogún mi ti rí sí mi bí i kìnnìún nínú igbó. Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
Jeremiah 12:8 in English
Jeremiah 12:8 · Berean Standard Bible
My inheritance has become to Me like a lion in the forest. She has roared against Me; therefore I hate her.
Context
6Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn
ìdílé
ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ,
wọ́n ti hó lé ọ lórí.
Má ṣe gbà wọ́n gbọ́
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára. 7Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀,
èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀.
Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́
lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. 8Ogún mi ti rí sí mi
bí i kìnnìún nínú igbó.
Ó ń bú ramúramù mọ́ mi;
nítorí náà mo kórìíra rẹ̀. 9Ogún mi kò ha ti rí sí mi
bí ẹyẹ kannakánná
tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?
Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ,
ẹ mú wọn wá jẹ. 10Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,
tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;
wọ́n ó sọ oko dídára mi di
ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.