Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

Jeremiah 12:10 in English

Jeremiah 12:10 · Berean Standard Bible

Many shepherds have destroyed My vineyard; they have trampled My plot of ground. They have turned My pleasant field into a desolate wasteland.

Context

8Ogún mi ti rí sí mi bí i kìnnìún nínú igbó. Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀. 9Ogún mi kò ha ti rí sí mi bí ẹyẹ kannakánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i? Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ, ẹ mú wọn wá jẹ. 10Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí. 11A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀ tí kò wúlò níwájú mi, gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání. 12Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà Olúwa yóò pa láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà; kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.