Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

Jeremiah 12:7 in English

Jeremiah 12:7 · Berean Standard Bible

I have forsaken My house; I have abandoned My inheritance. I have given the love of My life into the hands of her enemies.

Context

5Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́ṣẹ̀ sáré, tí àárẹ̀ sì mú ọ, báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje? Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà, bí ìwọ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé, kí ni ìwọ ó ṣe nínú ẹkùn odò Jordani? 6Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n ti hó lé ọ lórí. Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára. 7Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́. 8Ogún mi ti rí sí mi bí i kìnnìún nínú igbó. Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀. 9Ogún mi kò ha ti rí sí mi bí ẹyẹ kannakánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i? Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ, ẹ mú wọn wá jẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.