Onidajọ 5:25
Judges 5:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà; ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá.
Judges 5:25 in English
Judges 5:25 · Berean Standard Bible
He asked for water, and she gave him milk. In a magnificent bowl she brought him curds.
Context
23‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli Olúwa wí.
‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
láti dojúkọ àwọn alágbára.’ 24“Ìbùkún ni fún Jaeli,
aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́. 25Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;
ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá. 26Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,
ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,
òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,
ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin. 27Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ó wólẹ̀,
ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀.
Ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀;
níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.