Onidajọ 5:24
Judges 5:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìbùkún ni fún Jaeli, aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ, ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́.
Judges 5:24 in English
Judges 5:24 · Berean Standard Bible
Most blessed among women is Jael, the wife of Heber the Kenite, most blessed of tent-dwelling women.
Context
22Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,
nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn. 23‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli Olúwa wí.
‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
láti dojúkọ àwọn alágbára.’ 24“Ìbùkún ni fún Jaeli,
aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́. 25Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;
ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá. 26Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,
ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,
òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,
ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.