Onidajọ 5:22
Judges 5:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀, nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.
Judges 5:22 in English
Judges 5:22 · Berean Standard Bible
Then the hooves of horses thundered— the mad galloping of his stallions.
Context
20Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá
láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà. 21Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,
odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.
Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára! 22Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,
nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn. 23‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli Olúwa wí.
‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
láti dojúkọ àwọn alágbára.’ 24“Ìbùkún ni fún Jaeli,
aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.