Onidajọ 5:23
Judges 5:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli Olúwa wí. ‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò, nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa, láti dojúkọ àwọn alágbára.’
Judges 5:23 in English
Judges 5:23 · Berean Standard Bible
‘Curse Meroz,’ says the angel of the LORD. ‘Bitterly curse her inhabitants; for they did not come to help the LORD, to help the LORD against the mighty.’
Context
21Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,
odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.
Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára! 22Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,
nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn. 23‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli Olúwa wí.
‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
láti dojúkọ àwọn alágbára.’ 24“Ìbùkún ni fún Jaeli,
aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́. 25Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;
ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.