Native Bible

Judges 5:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ó wólẹ̀, ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀. Ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀; níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí.

Judges 5:27 in English

Judges 5:27 · Berean Standard Bible

At her feet he collapsed, he fell, there he lay still; at her feet he collapsed, he fell; where he collapsed, there he fell dead.

Context

25Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà; ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá. 26Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́, ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà, òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí, ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin. 27Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ó wólẹ̀, ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀. Ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀; níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí. 28“Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé, ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé, ‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé? Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’ 29Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn; àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.