Native Bible

Judges 14:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan.

Judges 14:1 in English

Judges 14:1 · Berean Standard Bible

One day Samson went down to Timnah, where he saw a young Philistine woman.

Context

1Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. 2Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” 3Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?” Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.