Onidajọ 14:2
Judges 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.”
Judges 14:2 in English
Judges 14:2 · Berean Standard Bible
So he returned and told his father and mother, “I have seen a daughter of the Philistines in Timnah. Now get her for me as a wife.”
Context
1Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. 2Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” 3Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?”
Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” 4(Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.)
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.