Onidajọ 14:4
Judges 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.)
Judges 14:4 in English
Judges 14:4 · Berean Standard Bible
(Now his father and mother did not know this was from the LORD, who was seeking an occasion to move against the Philistines; for at that time the Philistines were ruling over Israel.)
Context
2Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” 3Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?”
Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” 4(Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.) 5Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 6Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.