Onidajọ 14:3
Judges 14:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?” Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.”
Judges 14:3 in English
Judges 14:3 · Berean Standard Bible
But his father and mother replied, “Can’t you find a young woman among your relatives or among any of our people? Must you go to the uncircumcised Philistines to get a wife?” But Samson told his father, “Get her for me, for she is pleasing to my eyes.”
Context
1Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. 2Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” 3Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?”
Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” 4(Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.) 5Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.