Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná, yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yóò sì rán nínú pàǹtí igbó, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.

Isaiah 9:18 in English

Isaiah 9:18 · Berean Standard Bible

For wickedness burns like a fire that consumes the thorns and briers and kindles the forest thickets which roll upward in billows of smoke.

Context

16Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà, àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun. 17Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó, nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run, ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde. Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró. 18Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná, yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yóò sì rán nínú pàǹtí igbó, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè. 19Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí. 20Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun, síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n, ní apá òsì, wọn yóò jẹ, ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.