Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun, síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n, ní apá òsì, wọn yóò jẹ, ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.

Isaiah 9:20 in English

Isaiah 9:20 · Berean Standard Bible

They carve out what is on the right, but they are still hungry; they eat what is on the left, but they are still not satisfied. Each one devours the flesh of his own offspring.*

Context

18Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná, yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yóò sì rán nínú pàǹtí igbó, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè. 19Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí. 20Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun, síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n, ní apá òsì, wọn yóò jẹ, ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀. 21Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda. Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.