Isaiah 9:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
Isaiah 9:19 in English
Isaiah 9:19 · Berean Standard Bible
By the wrath of the LORD of Hosts the land is scorched, and the people are fuel for the fire. No man even spares his brother.
Context
17Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.
Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró. 18Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,
yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,
tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè. 19Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ
àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,
ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí. 20Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,
ní apá òsì, wọn yóò jẹ,
ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀. 21Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase
wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda.
Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò
Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.