Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà, àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.

Isaiah 9:16 in English

Isaiah 9:16 · Berean Standard Bible

For those who guide this people mislead them, and those they mislead are swallowed up.

Context

14Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù kúrò ní Israẹli, àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo, 15àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí, àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù. 16Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà, àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun. 17Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó, nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run, ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde. Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró. 18Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná, yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yóò sì rán nínú pàǹtí igbó, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.