Isaiah 9:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí, àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
Isaiah 9:15 in English
Isaiah 9:15 · Berean Standard Bible
The head is the elder and honorable man, and the tail is the prophet who teaches lies.
Context
13Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 14Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
kúrò ní Israẹli,
àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo, 15àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù. 16Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà,
àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun. 17Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.
Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.