Isaiah 9:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà sí ẹni náà tí ó lù wọ́n bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Isaiah 9:13 in English
Isaiah 9:13 · Berean Standard Bible
But the people did not return to Him who struck them; they did not seek the LORD of Hosts.
Context
11Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè. 12Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run.
Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. 13Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 14Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
kúrò ní Israẹli,
àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo, 15àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.