Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.

Isaiah 9:11 in English

Isaiah 9:11 · Berean Standard Bible

The LORD has raised up the foes of Rezin against him and joined his enemies together.

Context

9Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n— Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria— tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga àti gààrù àyà pé. 10Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán, a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀ ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn. 11Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè. 12Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn. Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run. Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀. 13Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà sí ẹni náà tí ó lù wọ́n bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.