Isaiah 63:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”; bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.
Isaiah 63:8 in English
Isaiah 63:8 · Berean Standard Bible
For He said, “They are surely My people, sons who will not be disloyal.” So He became their Savior.
Context
6Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;
nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu
mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.” 7Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa,
ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,
gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa,
bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo
tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli,
gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀. 8Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,
àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;
bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn. 9Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́
àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.
Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;
ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n
ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì. 10Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀
wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.
Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn
òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.