Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa, ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa, bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.

Isaiah 63:7 in English

Isaiah 63:7 · Berean Standard Bible

I will make known the LORD’s loving devotion and His praiseworthy acts, because of all that the LORD has done for us— the many good things for the house of Israel according to His great compassion and loving devotion.

Context

5Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́. Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́; nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró. 6Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi; nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.” 7Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa, ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa, bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀. 8Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”; bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn. 9Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là. Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà; ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.