Isaiah 63:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi; nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”
Isaiah 63:6 in English
Isaiah 63:6 · Berean Standard Bible
I trampled the nations in My anger; in My wrath I made them drunk and poured out their blood on the ground.”
Context
4Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi
àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé. 5Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.
Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;
nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi
àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró. 6Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;
nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu
mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.” 7Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa,
ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,
gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa,
bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo
tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli,
gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀. 8Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,
àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;
bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.