Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.

Isaiah 63:10 in English

Isaiah 63:10 · Berean Standard Bible

But they rebelled and grieved His Holy Spirit. So He turned and became their enemy, and He Himself fought against them.

Context

8Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”; bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn. 9Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là. Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà; ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì. 10Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà. 11Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn, 12ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.