Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

Isaiah 63:12 in English

Isaiah 63:12 · Berean Standard Bible

who sent His glorious arm to lead them by the right hand of Moses, who divided the waters before them to gain for Himself everlasting renown,

Context

10Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà. 11Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn, 12ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀, 13ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já? Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀; 14gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko, a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa. Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.