Isaiah 63:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já? Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀;
Isaiah 63:13 in English
Isaiah 63:13 · Berean Standard Bible
who led them through the depths like a horse in the wilderness, so that they did not stumble?
Context
11Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,
àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀
níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já,
pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?
Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán
Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn, 12ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀
láti wà ní apá ọ̀tún Mose,
ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn,
láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀, 13ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?
Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀; 14gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,
a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa.
Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín
láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo. 15Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i
láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.
Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?
Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a
ti mú kúrò níwájú wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.