Isaiah 63:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo. Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà? Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a ti mú kúrò níwájú wa.
Isaiah 63:15 in English
Isaiah 63:15 · Berean Standard Bible
Look down from heaven and see, from Your holy and glorious habitation. Where are Your zeal and might? Your yearning and compassion for me are restrained.
Context
13ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?
Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀; 14gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,
a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa.
Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín
láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo. 15Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i
láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.
Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?
Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a
ti mú kúrò níwájú wa. 16Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá
tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe;
ìwọ, Olúwa ni Baba wa,
Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ. 17Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ
tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?
Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.