Isaiah 61:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
Isaiah 61:5 in English
Isaiah 61:5 · Berean Standard Bible
Strangers will stand and feed your flocks, and foreigners will be your plowmen and vinedressers.
Context
3àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
irúgbìn Olúwa
láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn. 4Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́
wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;
wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà
tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn. 5Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;
àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ. 6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,
a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo. 7Dípò àbùkù wọn
àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
àti dípò àbùkù wọn
wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.