Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.

Isaiah 61:7 in English

Isaiah 61:7 · Berean Standard Bible

Instead of shame, My people will have a double portion, and instead of humiliation, they will rejoice in their share; and so they will inherit a double portion in their land, and everlasting joy will be theirs.

Context

5Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ. 6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo. 7Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn. 8“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀. Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn. 9A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.