Isaiah 61:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀. Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
Isaiah 61:8 in English
Isaiah 61:8 · Berean Standard Bible
For I, the LORD, love justice; I hate robbery and iniquity; in My faithfulness I will give them their recompense and make an everlasting covenant with them.
Context
6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,
a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo. 7Dípò àbùkù wọn
àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
àti dípò àbùkù wọn
wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn. 8“Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;
mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀.
Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn
èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn. 9A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn.
Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé
wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.” 10Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;
ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.
Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà
ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;
gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,
àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.