Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò; wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

Isaiah 61:4 in English

Isaiah 61:4 · Berean Standard Bible

They will rebuild the ancient ruins; they will restore the places long devastated; they will renew the ruined cities, the desolations of many generations.

Context

2láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, 3àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn. 4Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò; wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn. 5Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ. 6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.