Isaiah 57:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
Isaiah 57:5 in English
Isaiah 57:5 · Berean Standard Bible
who burn with lust among the oaks, under every luxuriant tree, who slaughter your children in the valleys, under the clefts of the rocks?
Context
3“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,
ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè! 4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?
Ta ni o ń yọ ṣùtì sí
tí o sì yọ ahọ́n síta?
Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,
àti ìran àwọn òpùrọ́? 5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta. 6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
àwọ̀n ni ìpín in yín.
Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
kí n dáwọ́ dúró? 7Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.