Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ, ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!

Isaiah 57:3 in English

Isaiah 57:3 · Berean Standard Bible

“But come here, you sons of a sorceress, you offspring of adulterers and prostitutes!

Context

1Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀; a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì ṣí ẹni tó yé pé a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi. 2Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé ń wọ inú àlàáfíà; wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú. 3“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ, ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè! 4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìran àwọn òpùrọ́? 5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.