Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìran àwọn òpùrọ́?

Isaiah 57:4 in English

Isaiah 57:4 · Berean Standard Bible

Whom are you mocking? At whom do you snarl and stick out your tongue? Are you not children of transgression, offspring of deceit,

Context

2Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé ń wọ inú àlàáfíà; wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú. 3“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ, ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè! 4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìran àwọn òpùrọ́? 5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta. 6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín; àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.