Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín; àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?

Isaiah 57:6 in English

Isaiah 57:6 · Berean Standard Bible

Your portion is among the smooth stones of the valley; indeed, they are your lot. Even to them you have poured out a drink offering and offered a grain offering. Should I relent because of these?

Context

4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìran àwọn òpùrọ́? 5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta. 6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín; àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró? 7Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà; níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín. 8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀, ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.