Isaiah 57:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà; níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
Isaiah 57:7 in English
Isaiah 57:7 · Berean Standard Bible
On a high and lofty hill you have made your bed, and there you went up to offer sacrifices.
Context
5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta. 6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
àwọ̀n ni ìpín in yín.
Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
kí n dáwọ́ dúró? 7Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín. 8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín
níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.
Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,
ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;
ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,
ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn. 9Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi
ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.
Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;
ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.