Isaiah 57:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ó sì sọ wí pé: “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
Isaiah 57:14 in English
Isaiah 57:14 · Berean Standard Bible
And it will be said, “Build it up, build it up, prepare the way, take every obstacle out of the way of My people.”
Context
12Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní. 13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
ni yóò jogún ilẹ̀ náà
yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.” 14A ó sì sọ wí pé:
“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.” 15Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí. 16Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
èémí ènìyàn tí mo ti dá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.