Isaiah 57:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
Isaiah 57:12 in English
Isaiah 57:12 · Berean Standard Bible
I will expose your righteousness and your works, and they will not profit you.
Context
10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,
ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’
Ẹ rí okun kún agbára yín,
nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín. 11“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù
tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,
àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi
tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?
Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́
tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi? 12Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní. 13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
ni yóò jogún ilẹ̀ náà
yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.” 14A ó sì sọ wí pé:
“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.