Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.

Isaiah 57:10 in English

Isaiah 57:10 · Berean Standard Bible

You are wearied by your many journeys, but you did not say, “There is no hope!” You found renewal of your strength; therefore you did not grow weak.

Context

8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀, ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn. 9Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín. Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré; ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú! 10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín. 11“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi? 12Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.