Isaiah 57:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú sá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ènìyàn tí mo ti dá.
Isaiah 57:16 in English
Isaiah 57:16 · Berean Standard Bible
For I will not accuse you forever, nor will I always be angry; for then the spirit of man would grow weak before Me, with the breath of those I have made.
Context
14A ó sì sọ wí pé:
“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.” 15Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí. 16Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
èémí ènìyàn tí mo ti dá. 17Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú;
síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀. 18Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.