Isaiah 57:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
Isaiah 57:17 in English
Isaiah 57:17 · Berean Standard Bible
I was enraged by his sinful greed, so I struck him and hid My face in anger; yet he kept turning back to the desires of his heart.
Context
15Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí. 16Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
èémí ènìyàn tí mo ti dá. 17Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú;
síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀. 18Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá, 19ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
ni Olúwa wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.