Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀, kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn; bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja.

Isaiah 5:27 in English

Isaiah 5:27 · Berean Standard Bible

None of them grows weary or stumbles; no one slumbers or sleeps. No belt is loose and no sandal strap is broken.

Context

25Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè sì wárìrì, òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀. 26Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà, yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀. Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán. 27Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀, kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn; bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja. 28Àwọn ọfà wọn múná, gbogbo ọrun wọn sì le; pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle. 29Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún, wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún, wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.